Home ÀKỌ̀TUN Màá bẹ̀rẹ̀ si pín èròjà ìdẹ̀rùn fún ìgbélé Covid-19 fáwọn aláìní l’ọsẹ yìí- Seyi Makinde
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 22, 2020

Màá bẹ̀rẹ̀ si pín èròjà ìdẹ̀rùn fún ìgbélé Covid-19 fáwọn aláìní l’ọsẹ yìí- Seyi Makinde

Màá bẹ̀rẹ̀ si pín èròjà ìdẹ̀rùn fún ìgbélé Covid-19 fáwọn aláìní l’ọsẹ yìí- Seyi Makinde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lílò aṣọ ìbòjú yóò di ọ̀ranyàn l’Oyo, ìjọba mi ń ṣe mílíọnù kan aṣọ ìbòjú- Makinde

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní òun ti gùnlé ọ̀gbìn irè oko fún ìpèsè oúnjẹ lẹ́yìn àrùn Coronavirus.

Onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde tí kéde pé, ìjọba òun ti pinnu láti pèsè aṣọ ìbòjú tó to mílíọ̀nù kan fáwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,

Èyí jẹ́ ọ́nà kan láti gbógun ti ìtànkálẹ̀ àrùn Coronavirus.

Gómìnà Mákindé, ẹni tó sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń báwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílé ìjọba ni Agodi n’ilu Ìbàdàn tún ṣàlàyé pé, aṣọ ìbòjú náà ló sèrànwọ́ fún àwọn orílẹ̀ èdè kan lagbaye, láti borí àrùn Covid-19.

Gómìnà fikùn un pé ìjọba yóò gbà ọgọ́rùn-ún Aránsọ (Tailor) láti rán àwọn ìbòjú náà, èyí tí yóò pọn ni dandan fáwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti máa lo aṣọ ìbòjú ní ìgboro.

Ó sọ̀rọ̀ lórí ìpèsè èròjà ìdẹ̀rùn fún aráàlú lásìkò igbele Covid-19 yìí, pe àkójọpọ̀ iye àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti wá ńlẹ̀ báyìí,

Eyií tó mú kó rọrùn láti mọ àwọn aláìní tí yóò jàǹfààní ètò ìdẹ̀rùn náà.

“Pẹ̀lú àkójọpọ̀ àkọsílẹ̀ olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ taa ṣe, ó jẹ ká mọ àwọn èèyàn tó jẹ́ aláìní, ó sì seese ká bẹ̀rẹ̀ si pín èròjà ìdẹ̀rùn fún wọn, kí ọsẹ yìí tó bùse”.

Bákan náà ni Gómìnà Mákindé tún kéde pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kò ní wọlé padà sí ẹnu iṣẹ́ mọ́ lọjọ́ Aje,

Ó tún di ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin, kí wọ́n tó padà sí ẹnu iṣẹ́.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìpèsè oúnjẹ, Gómìnà ni ó ṣeéṣe kí oúnjẹ fẹ́ wọ́n lẹ́yìn àrùn Coronavirus,

ìdí sì rèé tíjọba òun fi ń gbaradi fún ọ̀gbìn irè oko báyìí, kí oúnjẹ leè pọ̀ yanturu tí àrùn Covid-19 bá lọ ń lẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…