Ènìyàn 86 ní àrùn apinni léèmí coronavirus lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní Nàìjíríà
Ènìyàn 86 ní àrùn apinni léèmí coronavirus lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní Nàìjíríà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ó ti pé ẹgbẹ̀ta lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n 627 ènìyàn tó ti ní àrùn apinni léèmí coronavirus ní Nàìjíríà, lẹ́yìn tí wọ́n tún rí ènìyàn mẹ́rìndínláàdọ́rún lọ́jọ́ kan ṣoṣo.
Òǹkà yìí ló tí ì pọ̀ jùlọ láti ìgbà tí àrùn náà tí rá pálá wọ Nàìjíríà.
Àádọ́rin ènìyàn lára àwọn tuntun yìí ló wá láti ìpínlẹ̀ Èkó.
Èyí wáyé lẹ́yìn tí Ìjọba ìpínlẹ̀ náà kéde lópin ọ̀sẹ̀ pé òun ti fi kún oye ènìyàn tí òun ń ṣe àyẹ̀wò fún, tó sì tún ti dá àwọn ibùdó àyẹ̀wò sílẹ̀ ní Ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC
Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…