Home ÀKỌ̀TUN Iná sọ níbùdó aṣàtìpó ní Borno; ẹ̀mí mẹrìnlá sọnù!
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 20, 2020

Iná sọ níbùdó aṣàtìpó ní Borno; ẹ̀mí mẹrìnlá sọnù!

Iná sọ níbùdó aṣàtìpó ní Borno; ẹ̀mí mẹrìnlá sọnù!

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní ó kéré tán èèyàn mẹ́rìnlà ni ó ti kú tí èèyàn mẹ́ẹ̀dógún sì farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ iná kan tó jó ní ibùdó àwọn aṣàtìpó ti ìkọlù Boko Haram lé kúrò nílé wọn ní ìpínlẹ̀ Borno ní Nàìjíríà.

Àjọ náà ní ọjọ́bọ ni iná náà sẹ́ yọ ní Ngala ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Borno tó wà ní Àríwá Nàìjíríà tí ó súnmọ́ ibodè Cameroon.

Wọ́n ní ìṣẹ̀lẹ̀ yí jẹ́ eléyìí tó burú jù nínú àwọn àjálù tó ń wáyé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yí.

Iléeṣẹ́ tó ń mójútó ètò ìrànlọ́wọ́ fáwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá nílẹ̀ Africa (Ocha) sọ pé ó ti lé ní ìṣẹ̀lẹ̀ iná jíjò méjìlá tó ti ṣẹlẹ̀ láwọn ibùdó aṣàtìpó láàrin oṣù kan sẹ́yìn.

Bẹ́ẹ̀ ló sọ pé ilégbèé ọgọ́rùn ún mẹ́ta ló ti jó tí èyí sì sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn di aláìnílé lórí.

Àwọn òṣìṣẹ́ ìrànwọ́ ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti rí i pé àwọn ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tó fara káásá ìṣẹ̀lẹ̀ yí.

Wọn kò tí ì mọ ohun tó ṣokùnfà iná tó jó yìí.

Ààrẹ Nàìjíríà, Muhammadu Buhari ti sàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ yí gẹ́gẹ́ bí eléyìí tó burú jáì, tó sì ti pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …