Home ÀKỌ̀TUN Nàìjíríà pàdánù Abba Kyari ní ọmọ ọdún 81
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 18, 2020

Nàìjíríà pàdánù Abba Kyari ní ọmọ ọdún 81

Naijiria pàdánù Abba Kyari ní o̩mo̩ o̩dún 81

Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Ajakale arun buruku coronavirus wo orileede Naijiria ni ipari osu keji odun yii. Bi ere, bi awada, o bere si ni mu omo orileede yi ni okookan. Awon kan tile ni aisan ti ko le duro pe ni orileede yii ni, nitori ko feran ile olooru. Won ni ko tun feran eniyan dudu.
Ni ile ti o mo lonii yii, aisan yii ti mu eniyan mejedinleedegbeta (493), O doola eniyan to su mo igba, o ti semi eeyan metadinlogun legbodo.
Ara eniyan metadinlogun naa ni olori aabo Aare Mohammadu Buhari, Abba Kyari wa. Won bi oloogbe yi ni ojo ketadinlogun, osu kokanla odun 1938 ki iku to yowo re lawo ni ojo ketadinlogun osu kerin odun 2020. Osu kokanla odun yii ni ko ba pe omo odun mejilelogorin loke eepe.Irin ajo lo si ilu Germany ni baba yi ti ko aisan naa ni eyi to da jinnin- jinnin bo ile ise Aare ni igba ti aisan naa wo Aso Rock.
Gbogbo awon ti eru ba pe awon ni ajosepo pelu oloogbe yii ni won sare lo se ayewo sugbon ti ori ko opo yo. Awon gomina ati awon alagbara miiran to ko arun naa ni won ti gbadun bayii, amo “aisan lo see wo, ko si eni to ri tolojo se”. Orileede Naijira padanu Abba Kyari.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…