Home ÀKỌ̀TUN Láí Mohammed sọ pé aájò kí Nàìjíríà lè dára ló ṣokùnfà ikú Kyari
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 18, 2020

Láí Mohammed sọ pé aájò kí Nàìjíríà lè dára ló ṣokùnfà ikú Kyari

Láí Mohammed sọ pé aájò kí Nàìjíríà lè dára ló ṣokùnfà ikú Kyari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Mínísita fún ètò ìròyìn àti àṣà ní Nàìjíríà, Láì Mohammed ti sọ pé aájò Nàìjíríà ló pa Abba Kyari.

Lásìkò tó ń bá akọ̀ròyìn sọrọ, Láí sọ pé ènìyàn tó fi ara ṣiṣẹ́ fún Nàìjíríà, tó sì nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè náà ni Kyari jẹ́ nígbà ayé rẹ̀, tako bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe máa ń bu ẹnu àtẹ lù ú.

Láí sàpèjúwe Kyari gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan pàtàkì nínú ìṣèjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari, “nítorí pé kò sí nǹkan tí Ààrẹ fẹ ẹ ṣe tí kò ní í fi tó o létí. Òun ni alámọ̀ràn Ààrẹ.”

Gẹ́gẹ́ bí Láí ṣe sọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn kò mọ̀ nípa olóògbé pé ó fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ fún ìlú wa láti rí i pé iṣẹ́ àgbẹ̀ lọ sókè, ní pàtàkì jùlọ, ọ̀rọ̀ ìrẹsì gbingbin, àti ajílẹ̀ (fertilizer) wà lára àwọn nǹkan tó mú ní bàbàrà”

Láí tẹ̀síwájú láti sọ pé ọ̀rọ̀ Kyari dàbí Olóòtọ́ tí kìí lẹ́ni.

“Germany tó lọ ló ti kàgbákò àrùn apinni léèmí coronavirus, kò lọ fún ìgbádùn ara rẹ̀. Ó lọ nítorí ìlú ni. Ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná Nàìjíríà ló bá lọ síbẹ̀.

“Ààrẹ ní ikú rẹ̀ máa fì púpọ̀ nítorí pé ó jẹ́ ẹnìkan tí Ààrẹ gbáralé púpọ̀ fún ìmọ̀ràn.”

Wọ́n ti gbé òkú olórí àwọn òṣìṣẹ́ fún Ààrẹ Buhari, Abba Kyari dé ìlú Àbújá fún ìsìnkú.

Olùrànlọ́wọ́ fún Buhari lórí ẹ̀rọ ayélujára, Bashir Ahmad ló fi ìkéde náà síta.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …