Home ÀKỌ̀TUN Ìrìnàjò Abba Kyari láti ìgbà tó ti ní àrùn apinni léèmí Covid-19
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 18, 2020

Ìrìnàjò Abba Kyari láti ìgbà tó ti ní àrùn apinni léèmí Covid-19

Ìrìnàjò Abba Kyari láti ìgbà tó ti ní àrùn apinni léèmí Covid-19

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àrùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì ti pa olórí àwọn òṣìṣẹ́ lọ́fìísì Ààrẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari.

Agbẹnusọ fún Ààrẹ Buhari, Femi Adesina ló kéde ikú rẹ̀ lójú òpó twitter ní òru ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Gẹ́gẹ́ bí Adesina ṣe sọ, ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹrin ni Kyari kú.

Ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Kẹta, ọdún 2020, ni àjọ tó ń mójútó ìtànkálẹ̀ àrùn ní Nàìjíríà, NCDC, kéde pé Kyari ní àrùn apinni léèmí Covid-19.

Ọjọ́ díẹ̀ saájú ọjọ́ náà ni Kyari padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tó ti lọ dúnàá-dúrà okoòwò kan pẹ̀lú iléeṣẹ́ Siemens AG.

Ìlú Àbújá ni wọ́n ti kọ́kọ́ ń tọ́jú Kyari, kò tó ó di pé Ìròyìn sọ pé wọ́n ti gbé e wá sí ìlú Èkó ní ọjọ́ kọkàndínlógbọ̀n, oṣù kẹta, láti máa gba ìtọ́jú fún àrùn náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …