Home ÀKỌ̀TUN Mojèrè kò jèrè ọkọ, ẹ̀ṣẹ́ l’ọkọ fi gbẹ̀mí rẹ̀ l’Óǹdó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 15, 2020

Mojèrè kò jèrè ọkọ, ẹ̀ṣẹ́ l’ọkọ fi gbẹ̀mí rẹ̀ l’Óǹdó

Mojèrè kò jèrè ọkọ, ẹ̀ṣẹ́ l’ọkọ fi gbẹ̀mí rẹ̀ l’Óǹdó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní níbi tí èṣù làálú bá tí ń bínú, kò tọ̀nà kọ́lọ́gbọ́n èèyàn o tún máa dúró yọ wó ògidì ẹmu. À bì kínni ká ti pé tí bàbá àgbẹ̀ ẹni ọdún mọ́kànléláàdọ́rin náà ti wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Eric Olowokande tí àwọn ọlọ́pàá ṣàlàyé pé ó fi ẹ̀sẹ́ lu ìyàwó rẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mojèrè.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí èèyàn kan tó ṣojú rẹ̀ sọ ní kété tí ọ̀rọ̀ já jó alàgbà Olowokande lọ́wọ́ tán ló kánlùgbẹ́ tó sì na pápá bora láti mórí bọ́, ní páńpẹ́ àwọn ọlọ́pàá.

Àwọn tó ṣojú u wọn ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ ló ṣe bí ọ̀rọ̀ láàrin ìsọkọláyà méjéèjì yìí eléyìí tó di yánpọnyánrin láàrin wọn débi pé bàbá àgbàlagbà yìí yọ ẹ̀ṣẹ́ ti ìyàwó rẹ̀ yìí títí tí obìnrin náà fi ṣọdá kejì ayé.

Wọ́n ní ní lẹ́yẹ ò ṣọkà ni wọ́n gbé e dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí dókítà ti sọ ọ́ di mímọ̀ pé arábìnrin náà ti gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …