Home ÀKỌ̀TUN Ẹ máa jọ́sìn lórí ìtàkún ayélujára títí tí àrun Coronavirus yóò fi kásẹ̀ nílẹ̀ – CAN
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 15, 2020

Ẹ máa jọ́sìn lórí ìtàkún ayélujára títí tí àrun Coronavirus yóò fi kásẹ̀ nílẹ̀ – CAN

Ẹ máa jọ́sìn lórí ìtàkún ayélujára títí tí àrun Coronavirus yóò fi kásẹ̀ nílẹ̀ – CAN

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ọmọ ọ̀dọ̀ náà fi ọgbọ́n ṣe é.
Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kírísítì ní Nàìjíríà, CAN ti sọ pé òun kò tako Ìjọba àpapọ̀ lórí òfin kónílé-ó-gbélé tó gbé kalẹ̀.

Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Samson Olasupo Ayokunle ló sọ bẹ́ẹ̀ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú akọ̀ròyìn.

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà wáyé lẹ́yìn tí Ìròyìn kan sọ pé ẹgbẹ́ CAN ń fẹ́ kí Ìjọba àpapọ̀ gba àwọn Kírísítìẹ́nì láàyè láti ṣe ìsìn nínú àwọn ilé ìjọsìn wọn lásìkò ìgbélé Coronavirus.

Ó ní ipò ẹgbẹ́ náà ni pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì máa ṣe ìsìn lórí itàkùn àgbáyé títí tí ọ̀rọ̀ àrùn apinni léèmí Coronavirus tó wà lóde yóó fi kásẹ̀ nílẹ̀.

Ayokunle ṣo pé “Àjọ CAN kò le kọ ọ̀rọ̀ sí Ìjọba àpapọ̀ lẹ́nu.”

Ó tẹ̀síwájú pé “Ìjọba kò sọ pé kí á má jọ́sìn mọ́, ohun tí Ìjọba sọ ni pé ikú ń bẹ lóde, àti pé kí á jókòó sílé títí tí ikú yóó fi kọjá”

Lẹ́yìn náà lo pàrọwà sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì láti lo àkókò yí súnmọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà gbígbà, kí àsìkò yìí le tètè ré kọjá.

Ó ní kí àwọn Ìjọ lo àsìkò yìí láti pèsè oúnjẹ fún àwọn aláìní lágbègbè wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …