Home ÀKỌ̀TUN Òfin kónílé-ó-gbélé yóò tésìwájú ní Eko, Ogun àti Abuja fún ọjọ́ mẹ́rìnlá mìí – Buhari
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 14, 2020

Òfin kónílé-ó-gbélé yóò tésìwájú ní Eko, Ogun àti Abuja fún ọjọ́ mẹ́rìnlá mìí – Buhari

Òfin kónílé-ó-gbélé yóò tésìwájú ní Eko, Ogun àti Abuja fún ọjọ́ mẹ́rìnlá mìí – Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti sọ pé òfin kónílé-ó-gbélé yóò tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti Àbújá fún ọjọ́ mẹ́rìnlà míì nítorí àrùn apinni léèmí Coronavirus tó wà lóde.

Buhari ló sọ ọ̀rọ̀ náà nínú ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan tó wáyé lọjọ Ajé níbi tó ti bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀.

Ó ní òfin kónílé-ó-gbélé náà yóó bẹ̀rẹ̀ lọ́tun láti òru ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹrin ọdún 2020.

Buhari wá sèlérí pé Ìjọba ti gbé ìgbésẹ̀ láti sèrànwọ́ ohun amáyédẹrùn fún àwọn ìdílé tó lé ní mílíọ̀nù kan, yàtọ̀ sí mílíọ̀nù méjì tó ń sèrànwọ́ fún lọ́wọ́.

Ààrẹ sọ pé Ìjọba òun yóó sa ipá rẹ̀ láti rí i pé ayé dẹrùn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà lásìkò ìgbélé náà.

Lẹ́yìn náà ló fi mi ìmoore rẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ Nàìjíríà, papà á jùlọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti Àbújá, fún ìfaradà wọn lásìkò ìgbélé àkọ́kọ́.

Ó ní òun mọ̀ pé kò rọrùn láti wà nínú Ilé fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ṣùgbọ́n bí iye àwọn tó ń fara káásá àrùn náà ṣe ń peléke sí i ń kọ òun lóminú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…