Makinde, jọ̀ọ́ ebi ń pa wá, gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tóo fi dè wá – NURTW Oyo
Makinde, jọ̀ọ́ ebi ń pa wá, gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tóo fi dè wá – NURTW Oyo
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní n tó bá ń duni, níí pọ lọ́rọ̀ ẹni.
NURTW tó jẹ́ ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò ní ìpínlẹ̀ Oyo ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà Ṣèyí Mákindé lásìkò òfin kónílé-ó-gbélé látàrí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí coronavirus yìí.
Yorùbá ní ebi ń pá mí, kò ṣe é fi ìfé wí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni tí ebi ń pá, kìí gbọ́ àròyé kankan.
Èyí ló mú kí àwọn asáájú ẹgbẹ́ awakọ̀ èrò nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, NURTW, tí ìjọba tí fòfin dè, fi ń lọgun késí Gómìnà Ṣèyí Mákindé pé, kò gbé ẹsẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de ẹgbẹ́ náà.
Àtẹjáde kan tí àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ NURTW náà, nínú èyí táa tí rí Alhaji Abideen Olajide, táa mọ sì Ejiogbe, Alhaji Tajudeen Opeyemi, Alhaji Waheed Adeoyo, Alhaji Abass Amolese, Alhaji Raufu Ọlọruntobi àti Alhaji Lekan Aleshinloye fọwọ́sí lọ́jọ́ Ajé ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà, níbi tí wọ́n ti ń rawọ
Bákan náà ni wọn tún kesi àwọn èèyàn ti ọ̀rọ̀ yìí kàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti bá àwọn bẹ Gómìnà Mákindé pé, ìṣòro ńlá ni àìní owó lọ́wọ́ tó ń koju àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà láti ìgbà tí wọ́n ti fòfin de ẹgbẹ́ ọ̀hún lọ́dún kan sẹ́yìn.,
Kódà, àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ NURTW tí ìjọba fòfin dè náà tún késí àgbáríjọpọ̀ ẹ̀gbẹ́ àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ Ìbàdàn, CCII, àtàwọn èèyàn míràn tó jẹ́ èèkàn ìlú nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti bá àwọn bẹ gómìnà pé, ebi ń pá àwọn, kò sì gbé ẹsẹ kúrò lórí òfin tó fi dé àwọn.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…