Home ÀKỌ̀TUN Gómìnà Èkó s̩e ìlérí oúnje̩, owó, ààbò àti àwo̩n nǹkan ìdè̩ra míràn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 14, 2020

Gómìnà Èkó s̩e ìlérí oúnje̩, owó, ààbò àti àwo̩n nǹkan ìdè̩ra míràn

Gómìnà Èkó s̩e ìlérí oúnje̩, owó, ààbò àti àwo̩n nǹkan ìdè̩ra míràn
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Gomina ipinle Eko, Babajide Sanwo-olu ni ki awon Eko ma mikan mo. O ni eeto aabo to gbopan maa bere ni ale yii. O ni gbogbo inira ti awon odo kan n ko fun awon ara adugbo bii Agege, Abule-Egba, Oke koto, Iyana Ipaja ati awon adugbo to ku ni ijoba oun ti gbo. Eyi ni o si n je ki oun koko kilo fun awon obi ki onikaluku o so omo re mole, nitori pe ijoba ipinle Eko ko ni foju ire wo awon odaluru. Awon olopaa ati awon Soja ni won maa pawopo se ise naa.
O ni ounje sise ofe maa wa lara iranlowo ti ijoba maa bere ni ola si otunla. O ni eyi maa je ounje eekan lojumo.
Gomina ni eto tun ti wa lati fun awon to ku die kaa to fun ni awon owo iranwo kan,o ni eto naa ti n lo lowo lati le je ki akojo oruko awon to letoo sii de owo ijoba.
Gomina tun ni gbogbo awon olokoowo keekeke to ti yawo fun okoowo won ki arun coronavirus to de ni won ko ni san owo ele lori oun ti won ya fun osu meta gbako. O ni ijoba ti woye pe inira naa maa po ti arun ba lo ti awon olowo wa tun fe gba ojulowo ati ele.
Gomina Sanwo-olu tun ni gbogbo moto ti ijoba ti mu fun awon esun bii ki a gbe moto si ibi ti ko to, ki won ko eti ikun si ofin konile-o-gbele ati awon esun to fara pee ni won maa gba moto won ni ipari isede lai san owo kankan.
Gomina tun ni eto iranwo tun maa wa fun awon eya ti kii se Yoruba sugbon ti won n gbe Eko, o ni bee ni eto iranwo ko ni yo elegbejegbe tooto naa sile nitori pe arun to ba ti ba oju maa ba imu dandan.
Gomina wa ro awon ara ilu lati ni suuru daadaa ki won si fowo sowo po pelu ijoba ipinle Eko ki gbogbo awon alaale naa le lo ni irowo ati irose.
Gomina tun fi kun un pe aso ibomu ti ijoba ipinle Eko n se maa jade laipe fun irorun ara ilu naa ni sugbon ki awon eniyan gbele won fun ose meji to ku gege bi Aare Mohammadu Buhari se kede re nitori alaafia gbogbo wa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…