Ìjọba Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ fínfín ìgboro pẹ̀lú u apakòkòrò nítorí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí COVID-19
Ìjọba Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ fínfín ìgboro pẹ̀lú u apakòkòrò nítorí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí COVID-19
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní ogun tí yóó wọlé kó ni, ọ̀nà la tií pàdé ẹ̀.
Gbogbo ètò ló ti tò báyìí lórí ìgbìyànjú Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti ṣe àfọ̀mọ́ gbogbo ìgboro ìlú nítorí àrùn kòrónáfairọ̀ọ̀sì.
Oríṣìríṣi àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tó kún fún omi aró amúbíiná ló ti wà ní sẹpẹ́ lọ́fíìsì Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Níbẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbà fún àkànṣe iṣẹ́ náà yóó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kí ó tó di wí pé wọ́n wọ ìgboro lọ.
À ń retí Gómìnà tàbí àwọn aṣojú rẹ̀ láti bá àwọn oníròyìn ṣọ̀rọ̀ kí ètò náà tó gbìnàyá.Ìjọba Ọ̀yọ́ bẹ̀rẹ̀ fínfín ìgboro pẹ̀lú u apakòkòrò nítorí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí COVID-19
Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ
Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…