Ati fi páńpẹ́ òfin mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 92 tó ń dàlú rú – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó
Ati fi páńpẹ́ òfin mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 92 tó ń dàlú rú – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó
Fẹ́mi Akínṣọlá
Egbìnrìn ọ̀tẹ̀ , à ń sakitiyan àti pàkan, òmí-ìn n rú tú ú.
Ṣé kò wa rí bẹ́ẹ̀, niIéeṣẹ́ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Èkó sọ pé òun ti fi páńpẹ́ òfin mú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkuǹkùn méjìléláàdọ́rùn káàkiri ìpínlẹ̀ ọ̀hún.
Alukoro iléeṣẹ́ náà, Bala Elkana ló fi ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn.
Ó ní ọ́fíísì Ọlọ́pàá tó wà ní Ikorodu, pẹ̀lú ajọṣepọ̀ ẹ̀ka tó ń gbógun ti ìwà ìdigunjalè, SARS, ló mú àwọn afurasí náà.
Elkana ní lára àwọn tí wọ́n fi páńpẹ́ òfin mú ni Toheeb Sanusi, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún, àti Adewale Adesina, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún lágbègbè Benson, ní Ikorodu.
Ó ṣàlàyé pé wọ́n ká ohun ìjà olóró bí àdá àti ìbọn ìbílẹ̀ kan mọ́ àwọn afurasí náà lọ́wọ́ , èyí tí wọ́n jẹ́wọ́ pé wọ́n fẹ́ lò ó láti fi sọsẹ́.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…