Adarí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì, Boris Johnson ti kúrò nílé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n ṣètọ́jú fún àrùn Coronavirus.
Adarí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì, Boris Johnson ti kúrò nílé ìwòsàn lẹ́yìn tí wọ́n ṣètọ́jú fún àrùn Coronavirus.
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì ni ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta ọ̀hún kò ní tíì padà sẹ́nu iṣẹ́ báyìí, ṣùgbọ́n yóó má ṣiṣẹ́ láti ilé rẹ̀ tó wà ní Chequers.
Wọ́n gbé Ọ̀gbẹ́ni Johsnon lọ ilé ìwòsàn St. Thomas ní ìlú London lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ti lùgbàdì àrùn Coronavirus.
Àfẹ́sọ́nà rẹ̀, Carries Symonds, tó wà nínú oyún fi ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ léde lójú òpó Twitter rẹ̀, tó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà fún àdúrótì wọn fún gbogbo ìgbà tí adarí Ìjọba ọ̀hún fi wà ní ilé ìwòsàn.
Ó ní “Àwọn ìgbà kan wà tí mo ti rò ó pin pé kò le sí ọ̀nà àbáyọ mọ́, mo sì ń gbàdúrà fún gbogbo àwọn èèyàn tí wọ́n wà ní irú ipò yìí.”
Obìnrin náà tí ìrètí wà pé yóó bí ọmọ ọkùnrin ní oṣù méjì sí àsìkò yìí tí wà ní ìdánìkànwà, ṣùgbọ́n kò tíì sàyẹ̀wò bóyá ó ní àrùn náà lára.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…