Home ÀKỌ̀TUN Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò bá àwọn ọmọ Najiria sọ̀rọ̀ láago méje alẹ́ òní
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 13, 2020

Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò bá àwọn ọmọ Najiria sọ̀rọ̀ láago méje alẹ́ òní

Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò bá àwọn ọmọ Najiria sọ̀rọ̀ láago méje alẹ́ òní

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Muhammadu Buhari yóó bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ láago méje ìrọ̀lẹ́ òní.

Olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Ààrẹ lórí ọ̀rọ̀ tó ń lọ, Femi Adesina ló kéde bẹ́ẹ̀ nínú àtẹjáde kan tó fi ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn.

Adesina sọ pé “A rọ àwọn iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán àti asọ̀rọ̀mágbèsì láti darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n Ìjọba àpapọ̀ fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà.”

Ọpọ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti ń retí kí Ààrẹ báwọn sọrọ lórí ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Coronavirus tó wà lóde, pa pà á jùlọ lórí òfin kónílé-ó-gbélé kónílé-ó-gbélé tó gbé kalẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Èkó, Ògùn àti Àbújá.

Ẹ kú ojú lọ́nà

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…