Home ÀKỌ̀TUN Ìjìyà ‘Frog Jump’ ni ọlọpàá India fi jẹ àwọn tí kò bọwọ fún òfin kónílé-o-gbélé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 12, 2020

Ìjìyà ‘Frog Jump’ ni ọlọpàá India fi jẹ àwọn tí kò bọwọ fún òfin kónílé-o-gbélé

Ìjìyà ‘Frog Jump’ ni ọlọpàá India fi jẹ àwọn tí kò bọwọ fún òfin kónílé-o-gbélé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Oríṣìríṣi ìjìyà ni ìjọba orílẹ̀-èdè India ti gbà nípaṣẹ̀ àwọn agbófinró láti máa jẹ àwọn kọ̀lọ̀rànsí tí kò bọ̀wọ̀ fún òfin kónílé-ó-gbélé ní Orílẹ̀-èdè India nítorí àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí coronavirus.

Bí àwọn awakọ tó bá jáde ṣe ń gba ìjìyà sísan owó ìtanràn ní Jabalpur ní orílẹ̀-èdè India, ni àwọn míràn ń jìyà fífi ara wọn sáré bíi ọ̀pọ̀lọ́ nítorí kí wọ́n le gbọ́ràn láti jókòó sílé wọn láì tan àrùn apinni léèmí náà coronavirsu kálẹ̀ .

Ènìyàn 7, 529, ló ti lùgbàdì àrùn apinni léèmí coronavirus ní India tí èèyàn 242;tí jáde láyé, nígbà tí èèyàn 653 ti bọ́ lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn náà.

Àdúrà làsìkò yí gbà pẹ̀lú ìfaradà láti ṣẹ́gun àrùn apinni léèmí Coronavirus–Ààrẹ Buhari

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Buhari kí àwọn ọmọ Nàìjíríà kú àfaradà bí gbogbo nǹkan ṣe ń lọ lásìkò Coronavirus yìí

Nínú ọ̀rọ̀ ìkínni kú ọdún Àjíǹde tó fi ṣọwọ́ sáwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ààrẹ Buhari ṣàlàyé pé ìgbáyégbádùn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kìí ṣé oun tó ṣe é dúnàádúrà lé lórí ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ ààbò àti àlàáfíà aráàlú ṣe kókó.
Ààrẹ fi kún un pé, ó wu òun kí wọ́n jáde ṣọdún Àjíǹde, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Covid 19 yìí ń gbẹ́mìí kúkúrú gígùn, o sì jẹ́ ohun ìbànújẹ́.
Ààrẹ wá fikún un pé,ki àwọn ènìyàn o tẹ̀lé òfin kónílé-ó-gbélé tí Ìjọba ti pàṣẹ kónílé-ó-gbélé o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…