Home ÀKỌ̀TUN Sinimá ní kóòtù, adájọ́ pàṣẹ kí ọlọ́pàá kó gbogbo èrò tó wá síbi ìgbẹ́jọ́ l’Ọ́ṣun nítorí Coronavirus
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 10, 2020

Sinimá ní kóòtù, adájọ́ pàṣẹ kí ọlọ́pàá kó gbogbo èrò tó wá síbi ìgbẹ́jọ́ l’Ọ́ṣun nítorí Coronavirus

Sinimá ní kóòtù, adájọ́ pàṣẹ kí ọlọ́pàá kó gbogbo èrò tó wá síbi ìgbẹ́jọ́ l’Ọ́ṣun nítorí Coronavirus

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìran kọjá wíwò ní ilé ẹjọ́ Májísírètì àgbà kan Ọ̀ṣun ní Ọjọ́rú nígbà tí Adájọ́ Májísírètì àgbà kan, Ọ̀mọ̀wé Oluṣẹgun Ayilara pàṣẹ kí ọlọ́pàá kó gbogbo àwọn èrò tó wá wòran ìgbẹ́jọ́ ní kóòtù náà.

Arákùnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún àti arábìnrin ẹni ọdún márùndíláàdọ́ta kan làwọn agbófinró gbé wa síwájú ilé ẹjọ́ náà pé wọ́n tako òfin kónílé-ó-gbélé tí Ìjọba ìpínlẹ̀ náà gbé kalẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

Nígbà tí adájọ́ Májísírètì tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà wọlé dé tó bá ọ̀pọ̀ èrò ní yàrá ìgbẹ́jọ́ ló bá pàṣẹ pé kí àwọn ọlọ́pàá kó gbogbo wọn láì ku ẹnìkan sátìmọ́lé.

Kò sí ìdí méjì, adájọ́ ní wọ́n ti tẹ òfin ìjìnàsíra ẹni tí Ìjọba gbé kalẹ̀ láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ arun apinni léèmí coronavirus nípìńlẹ̀ náà lójú.

Nígbà tó yá tí adájọ́ náà jèbùrẹ́ ló wá ní kí wọ́n ya àwọn tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí àwọn afurasí sọ́tọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…