Home ÀKỌ̀TUN Coronavirus mú kí ìjọba àpapọ̀ ṣe àdínkù ètò iṣúná ọdún 2020
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 10, 2020

Coronavirus mú kí ìjọba àpapọ̀ ṣe àdínkù ètò iṣúná ọdún 2020

Coronavirus mú kí ìjọba àpapọ̀ ṣe àdínkù ètò iṣúná ọdún 2020.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí coronavirus ti mú kí Ìjọba àpapọ̀ ṣe àdínkù ètò ìṣúná orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ọdún 2020 yìí.

Ìjọba àpapọ̀ ti fi ètò ìṣúná ọ̀hún ṣọwọ́ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l’Abuja nínú èyí tí Ìjọba ti dín owó níná kù láwọn ẹ̀ka kan.

Kódà ìpàdé wáyé láàrin àwọn aláṣẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà àti Mínísítà ètò ìnáwó, Zainab Ahmed pẹ̀lú olùdarí Ilé iṣẹ́ epo rọ̀bì Nàìjíríà, Mele Kyari.

Ìwé tí Ìjọba fi ṣọwọ́ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fihàn pé ìjọba ti ṣe àdínkù ìdá ogún nínú iṣẹ́ àkànṣe láwọn ẹ̀ka Ìjọba gbogbo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…