Home ÀKỌ̀TUN A ti rí ènìyàn 232 tó ní ìfarakánra pẹ̀lú àwọn méjì tó ní Coronavirus ní ìlú Offa’
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 10, 2020

A ti rí ènìyàn 232 tó ní ìfarakánra pẹ̀lú àwọn méjì tó ní Coronavirus ní ìlú Offa’

A ti rí ènìyàn 232 tó ní ìfarakánra pẹ̀lú àwọn méjì tó ní Coronavirus ní ìlú Offa’

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti ní àwọn ti rí ènìyàn méjìlélọ́gbọ̀nlénígba tó ní ìfarakánra pẹ̀lú àwọn méjì tó ti ní àrùn apinni léèmí Coronavirus ní ìlú Offa.

Akọ̀wé ètò ìròyìn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara,Ajakaiye Rafiu tó bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣọ pé ìjọba ti gbé gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ kí wọ́n gbé láti rí i pé òfin kónílé-ó-gbélé tí yóó bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Offa kẹ́sẹjárí.

Arákùnrin Rafiu ní lára ìgbésẹ̀ ìjọba ní láti pèsè oúnjẹ fún àwọn ènìyàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò le è kárí àwọn ènìyàn ní ìlú náà, àmọ́ àwọn arúgbó, opó, oníṣẹ́ ọwọ́ ,àwọn àkàndá ènìyàn ni yóó rí àwọn oúnjẹ ìrànwọ́ yìí gbà ní ọwọ́ Ìjọba.

Bákan náà ló ní ìjọba ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú Olofa ti ìlú Offa, àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ àti àwọn ẹ̀sọ́ agbófinró láti rí i pé àwọn ènìyàn tẹ̀lé òfin kónílé-ó-gbélé gbele.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Olofa ti ìlú Offa nígbà tí ó ń fi èrò rẹ̀ hàn sọ pé Ìjọba náà gbìyànjú, tí ó sì pèsè ìrẹsì àti sẹ̀mó fún àwọn ènìyàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …