Home ÀKỌ̀TUN A ti lọ, a ti dé! Ìjọba forí jin Naira Marley àti Gbadamosi lórí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọkọ Funke Akindele
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 10, 2020

A ti lọ, a ti dé! Ìjọba forí jin Naira Marley àti Gbadamosi lórí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọkọ Funke Akindele

A ti lọ, a ti dé! Ìjọba forí jin Naira Marley àti Gbadamosi lórí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọkọ Funke Akindele

Fẹ́mi Akínṣọlá

Máa lọ lálàáfíà, àmọ́ má ṣe d’ẹ́ṣẹ̀ mọ́. Báyìí ni ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ṣe foríjin olórin tàkasúféè, Azeez Fashola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Naira Marley àti olóṣèlú, Babatunde Gbadamosi pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ lórí
ẹ̀sùn títàpá sí òfin kónílé-ó-gbélé tó wà lóde nítorí àrùn apinni léèmí Coronavirus.

Ìjọba Èkó fi ẹ̀sùn náà kàn wọ́n lẹ́yìn tí wọ́n lọ síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Abdul-Rasheed Bello, ọkọ Funke Akindele.

Ọjọ́rú ló yẹ kí wọ́n fojú ba iléẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ agbẹjọ́rò wọn, Ebun-Olu Adegboruwa (SAN) ṣàlàyé pé ìjọba ti dáríjìn wọ́n, ó sì ti wọ́gilé ẹ̀sùn oníkókó mẹ́rin tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Agbẹjọ́rò àgbà Adegboruwa ní ìjọba dáríjìn wọ́n pẹ̀lú gbèdéke pé wọ́n gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari àti Gómìnà Babajide Sanwo-Olu ìpínlẹ̀ Èkó.
Bákan náà ní Amòfin àgbà náà ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Babajide Sanwo-Olu láti jáwé oríjìn fún Funke Akindele àti ọkọ rẹ̀ lóríi òòlù òfin tí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó fi jàn wọ́n látàrí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …