Home ÀKỌ̀TUN Ọlọ́pàá gba béèlì Naira Marley, Gbadamọṣi; ṣùgbọ́n yóò fojú b’alé ẹjọ́ o
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 9, 2020

Ọlọ́pàá gba béèlì Naira Marley, Gbadamọṣi; ṣùgbọ́n yóò fojú b’alé ẹjọ́ o

Ọlọ́pàá gba béèlì Naira Marley, Gbadamọṣi; ṣùgbọ́n yóò fojú b’alé ẹjọ́ o

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó ti gba béèli gbajúgbajà akọrin tàkasúféè n nì, Naira Marley àti olùdíje kan fún ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Èkó, Babatunde Gbadamọṣi àti aya rẹ̀ lórí ẹ̀sùn pé ó lọ síbi àpèjẹ lásìkò tí Ìjọba pàṣẹ kónílé-ó-gbélé ní ìpínlẹ̀ Èkó.

Naira Marley àtàwọn èèyàn kan fojú hàn níbi àpèjẹ ọjọ́ ìbí ọkọ èèkàn òṣèré sinimá, Fúnkẹ́ Akíndélé Bello lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Àwọn ọlọ́pàá gba béèlì Marley lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun nígbà tí àwọn ilé ẹjọ́ kò ṣiṣẹ́ nítorí àjàkálẹ̀ àrùn coronavirus tó ń jà káàkiri.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn táa gbọ́, láti iléeṣẹ́ ọlọ́pàá yóó fojú wọn ba ilé ẹjọ́ láti jẹ́jọ́ ẹ̀sùn náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…