Home ÀKỌ̀TUN Mo ti ká Ajimobi pè̩lú obìnrin mìíràn lé̩è̩mejì – Florence Ajimobi

Mo ti ká Ajimobi pè̩lú obìnrin mìíràn lé̩è̩mejì – Florence Ajimobi

Mo ti ká Ajimobi pè̩lú obìnrin mìíràn lé̩è̩mejì – Florence Ajimobi

Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínka Àlàbí

Ko si ibi ti ese ko si, eyi lo maa n mu ki awon agba Yoruba maa so pe “eni eegun n le ki o maa roju nitori pe bi o se n re ara aye naa lo n re ara orun”.
Arabinrin Florence Ajimobi ti o je iyawo gomina ana ni ipinle Oyo ni o tenu b’oro ohun toju re ti ri.
O ni imoran gidi ni fun awon obinrin to wa ni ile oko, o ni bii eemeji otooto ni oun ti ka oko oun pelu obinrin miiran, ti o si bebe idariji, o ni asise ni, oun si forijii.
Aya Ajimobi ni idariji gidi gan-an wa ni odo Olorun. O ni oun gba pe ko si bi iru nnkan bee ko se ni maa waye nitori pe awon obinrin oloju komu ko lo po ni ilu.
O ni ti won ba si ti yo toju won tan, oun ni oun si tun ni oko oun losan ati loru.
O ni opo ile to daru lonii, obinrin naa ni ebi to po ju. O ni ki obinrin ka oko re lodo obinrin miiran ki eniyan wa bara je ju bi o ti ye lo maa n dale ru patapata ni. O ni eyi si ni eni to n da oko yin laamu gan-an n fe.
Aya Ajimobi tun gba awon obinrin nimoran pe ki won ye ma bu oko won tabi binu lori asise oko ju bi o ti ye lo. O ni eyi lo maa n fa ifowo Kan ara eni. O ni eyi ti o maa n tete mu ki igbeyawo tu ka.
Aya Ajimobi ni boya iriri naa kun ohun ti o je ki oun ri ile oun to,o ni oun ko gbe lodo baba oun. O ni baba miiran ti mama oun fe lo to oun dagba ni eyi ti ko dara to. O ni iyen naa wa lara ohun ti o je ki oun ba ori oun da majemu pe oun ko ni fi ile oko sile fun obinrin miiran.
Aya Ajimobi tu keke oro ju bayii lo lori ero ayelujara Twitter pelu omo re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…