Home ÀKỌ̀TUN Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ya bo ibùdó ìdìbò láti gba oúnjẹ kòrónáfairọ̀ọ̀sì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 8, 2020

Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ya bo ibùdó ìdìbò láti gba oúnjẹ kòrónáfairọ̀ọ̀sì

Àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ya bo ibùdó ìdìbò láti gba oúnjẹ kòrónáfairọ̀ọ̀sì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí ń tí a mọ̀ ọ́ jẹ bá ti tán, kí n tí a kìí jẹ papà á ó má ṣàfira ní o ,bí àwọn àgbà se fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ebi kìí wọ nú, kọ́rọ̀ míì ó wọ̀ ọ́ .

Èyí ló mú bí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ọṣun ti lọ péjú sáwọn ibùdó ìdìbò kóówá wọn láti gba àwọn oúnjẹ ìrànwọ́, èyí tí Ìjọba ìpínlẹ̀ náà pinnu fúnwọn.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọṣun kéde pé àwọn ti tẹ́wọ́ gba àwọn ohun amáyérọrùn tí wọ́n bèèrè fún láti bomi rọ ìrora táráàlù leè má a fara kó nípaṣẹ̀ àṣẹ ìgbélé tí Ìjọba pa.

Ìjọba ìpínlẹ̀ náà kéde pé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ogún àpò ìrẹsì ní wọ́n yóó pín káàkiri ibùdó ìdìbò ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́wàá tó wà káàkiri ìpínlẹ̀ náà. Eléyìí tó fihàn pé àpò ìrẹsì méjì méjì ni yóó kan ibùdó ìdìbò kọ̀ọ̀kan.

Kí agogo mẹ́jọ ààbọ̀ tó lù làwọn èèyàn ti péjú sáwọn ibùdó ìdìbò káàkiri ìlú Oṣogbo tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…