Home ÀKỌ̀TUN Gómìnà Makinde ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń gbèrò lórí sísọ ìbòjú wíwọ̀ dí dandan fún aráàlú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 7, 2020

Gómìnà Makinde ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń gbèrò lórí sísọ ìbòjú wíwọ̀ dí dandan fún aráàlú

Gómìnà Makinde ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń gbèrò lórí sísọ ìbòjú wíwọ̀ dí dandan fún aráàlú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé olójú ò níí yajú ẹ̀ sílẹ̀ kí tàlùbọ̀ ó yí wọ̀ọ̀, ló mú kí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé sọ pé ó ṣeéṣe kí Ìjọba pàṣẹ lílò ìbòjú ní tipátipá fún àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà bí wọ́n bá fẹ́ jáde lọ ṣe ohunkóhun.

Gómìnà Mákindé sọrọ yìí lásìkò tó fi ń dáhùn ìbéèrè lórí iléeṣẹ́ Redio kan ní ìlú Ìbàdàn ní òwúrọ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá

Ó ní òun ti bẹ̀rẹ̀ sí níí rọ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ìsàkóso ètò ìgbógun ti àrùn náà nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò.

Gómìnà Mákindé ní òun ríi pé ìgbésẹ̀ kíkàn án nípá fún gbogbo èèyàn tó bá fẹ́ jáde láti máa lo ohun èlò ìdáàbòbò ìbòjú ní ìjọba orílẹ̀-èdè Czech Republic lò láti fi kojú àrùn náà, tí òun sì ríi pé ó ń jẹ́ fún wọn bí i idán.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…