Home ÀKỌ̀TUN Ilé ẹjọ́, kàńpá fún Wòlíì ‘Sọtítóbirẹ’ láti sèmọ́tótó ọwọ́ ẹ kó tó wọlé ẹjọ́ lásìkò kòróná fairọ̀ọ̀sì yìí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 6, 2020

Ilé ẹjọ́, kàńpá fún Wòlíì ‘Sọtítóbirẹ’ láti sèmọ́tótó ọwọ́ ẹ kó tó wọlé ẹjọ́ lásìkò kòróná fairọ̀ọ̀sì yìí

Ilé ẹjọ́, kàńpá fún Wòlíì ‘Sọtítóbirẹ’ láti sèmọ́tótó ọwọ́ ẹ kó tó wọlé ẹjọ́ lásìkò kòróná fairọ̀ọ̀sì yìí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní, ohun tó n ṣe Ògundélé kò se ajá ẹ̀,Ògundélé ń ronú bí yóó se pajá ẹ̀ bọ̀gun, ajá ẹ̀ ń ronú àti logún ọdún láyé.

Ìṣòro ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ báyìí fún gbajúgbajà òjíṣẹ́ Ọlọ́run Ìjọ Sọtítóbirẹ ni ìlú Akurẹ, Wòlíì Alfa babatunde báyìí nítorí bí gbogbo ayé ṣé ń du orí wọn kí wọ́n má kó àrùn apinni léèmí Covid 19 ni Wòlíì Sọtítóbirẹ ń du orí rẹ̀ níwájú adájọ́ Ilé ẹjọ́ gíga nílùú Akurẹ.

Wòlíì Babatunde ń jẹ́wọ́ ìjínigbé tí wọ́n fi kan òun àtàwọn ọmọ Ìjọ rẹ̀ mẹ́fà lórí ọmọdé jòjòló kan tó pòórá ní ilé ìjọsìn rẹ̀ ní oṣù Kọkànlá ọdún 2019.

Wòlíì Sọtítóbirẹ ń padà sí ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ tí àwọn ẹlẹ́rìí gbogbo sì ti ń wí tẹnu wọn níwájú Ilé ẹjọ́ láti mọ̀ bóyá ọwọ́ ìránsẹ́ Ọlọ́run náà mọ́ tàbí kò mọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Akọ̀ròyìn tó wà níbi ìgbẹ́jọ́ náà ṣàlàyé pé kí àwọn afurasí náà tó wọ Ilé ẹjọ́ ni wọ́n ti kọ́kọ́ ní kí wọ́n fọ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ń lọ lóde báyìí pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn apinni léèmí Covid 19.

Bákan náà ni wọ́n kò jẹ́ kí akọ̀ròyìn kankan wọlé sí yàrá ìgbẹ́jọ́ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…