Home ÀKỌ̀TUN Iṣẹ́ labiyamọ ń ṣe o, Davido pariwo síta lórí bó ṣe ń tọ́jú ọmọ tí Chioma fi sílẹ̀ fún
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 6, 2020

Iṣẹ́ labiyamọ ń ṣe o, Davido pariwo síta lórí bó ṣe ń tọ́jú ọmọ tí Chioma fi sílẹ̀ fún

Iṣẹ́ labiyamọ ń ṣe o, Davido pariwo síta lórí bó ṣe ń tọ́jú ọmọ tí Chioma fi sílẹ̀ fún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbajúgbajà akọrin tàkasúféè ni, David Adeleke tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Davido ti pariwo síta pé nǹkan kò rọrùn lórí títọ́jú ọmọ tí òun àti ìyàwó rẹ̀ Chioma bí látìgbà tí ìyá rẹ̀ ti wà ní ìgbélé ìyàsọ́tọ̀.

Chioma, ìyàwó Davido kó àrùn apinni léèmí Coronavirus eléyìí tí ọkọ rẹ̀ , Davido kéde fáyé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Nínú ọ̀rọ̀ kan tó fi síta lójú òpó ìkànì abẹ́yefò “Twitter” rẹ̀ Davido lọgun pé iṣẹ́ l’abiyamọ ń ṣe.

Lẹ́yìn tí àyẹ̀wò fihàn pé Chioma ti kó àrùn Coronavirus, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Davido ní òun ti ṣe àyẹ̀wò láti leè mọ̀ bóyá òun ní àrùn náà tàbí òun kò ní.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…