Home ÀKỌ̀TUN Gómìnà Ṣèyí Mákindé dágbére fún àrùn Coronavirus, yóò padà sẹ́nu iṣẹ́ ní àkọ̀tun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 6, 2020

Gómìnà Ṣèyí Mákindé dágbére fún àrùn Coronavirus, yóò padà sẹ́nu iṣẹ́ ní àkọ̀tun

Gómìnà Ṣèyí Mákindé dágbére fún àrùn Coronavirus, yóò padà sẹ́nu iṣẹ́ ní àkọ̀tun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Onímọ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ní òun ti padà lọ ṣe àyẹ̀wò ara òun lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti mọ̀ bóyá àrùn apinni léèmí Coronavirus ṣì wà lára òun tàbí ó ti lọ àti pé àyẹ̀wò méjéèjì báyìí ló fihàn pé ṣáká lara òun le.

Ní ọjọ́ Ajé tó kọjá ni Gómìnà Mákindé gbé e jáde lójú òpó abẹ́yefò twitter rẹ̀ pé àyẹ̀wò ti fihàn pé òun ní àrùn Coronavirus lára tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ wọ ìgbélé ìyàsọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìlànà àátẹ̀lé tí àwọn onímọ́tò nípa kòkòrò àrùn àti ìlera ṣe làá kalẹ̀ fún un.

Ìlàkalẹ̀ fun àyẹwò ẹni tó bá ní àrùn yìí kí ó tó leè gba ìwé ṣáká lara dá, ní láti ṣe àyẹ̀wò méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ èyí tí yóó fihàn pé kò ní àrùn náà mọ́; méjéèjì yìí sì ni Mákindé ṣe báyìí.

Nínú ọ̀rọ̀ tó fi sí ojú opo abẹ́yefò rẹ̀ Twitter , Gómìnà Ṣèyí Mákindé ní òun mọ rírí àdúrà àtìlẹ́yìn àti àdúrà àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lásìkò tí òun fi wà ní ìgbélé ìyàsọ́tọ̀ fún ìtọ́jú àrùn náà.

Ó fi kún un pé òun yóó sì padà sí ẹnu iṣẹ́ ní ọjọ́ Ajé.

Nínú ọ̀rọ̀ tó bá akọ̀ròyìn sọ, Kọmíṣọ́nnà fún ètò ìròyìn àti ìtanijí, Ọ̀gbẹ́ni Wasiu Ọlatubọsun ṣàlàyé pé àáyá bẹ́ẹ́lẹ̀ ó bẹ́ áré ni Gómìnà Mákindé fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ìpadàbọ̀ rẹ̀ báyìí pẹ̀lú pípadà sí ẹnu iṣẹ́ lẹ́yẹ ò ṣọkà láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò gbogbo láti lé àrùn apinni léèmí Coronavirus wọ̀gbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…