Home ÀKỌ̀TUN Boris Johnson, Ọlóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dèrò iléèwòsàn nítorí àrùn Coronavirus
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 6, 2020

Boris Johnson, Ọlóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dèrò iléèwòsàn nítorí àrùn Coronavirus

Boris Johnson, Ọlóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dèrò iléèwòsàn nítorí àrùn Coronavirus

Fẹ́mi Akínṣọlá

Kò jọ pé àrùn apinni léèmí Covid19 yìí mojú ẹnikẹ́ni o. Ní báyìí bí ìròyìn se fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Olóòtú Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Boris Johnson ti di èrò iléèwòsàn báyìí fún àwọn àyẹ̀wò gbogbo tó yẹ, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá tí àyẹ̀wò ti kọ́kọ́ fihàn pé ó ti kó àrùn apinni léèmí Coronavirus.

Àtẹ̀jáde kan láti iléeṣẹ́ Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì tí a mọ̀ sí Downing Street ṣàlàyé pé ní àṣálẹ́ ọjọ́ Àìkú ni wọ́n gbé e lọ sí iléèwòsàn kan ní ìlú Lọndọn nígbà tí ó ń ṣàfíhàn àìsàn náà tófimọ́ ara gbígbóná.

Àmọ́ṣá iléeṣẹ́ Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì ṣàlàyé pé òun ṣì ní àkóso Ìjọba wà ní ìkáwọ́ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní ìrètí wà pé yóó léwájú ìpàdé kan tí yóó wáyé lórí ọ̀rọ̀ àrùn Coronavirus ní Òwúrọ ọjọ́ Ajé.

Wọ́n ní ìgbésẹ̀ ìtọ́jú lásán ni gẹ́gẹ́ bí àmọ̀ràn Dókítà tó ń tọ́jú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ ìròyìn se fìdí rẹ̀ múlẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Johnson yóó sun orun alẹ́ ọjọ́ kan níbẹ̀ láti leè ṣe àwọn àyẹ̀wò gbogbo tó bá yẹ.

Láti ilé rẹ̀ ni Olóòtú Ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́ṣì náà ti ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo láti ìgbà tí àyẹ̀wò ti gbé e jáde ní ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta pé ó ní àrùn náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …