Home ÀKỌ̀TUN Nítorí ẹbọra kòrónà, Ọọ̀nirìṣà,Ògúnwùsì ṣàmúlò ìṣẹ̀ṣe orò bi ọ̀nà àbáyọ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 3, 2020

Nítorí ẹbọra kòrónà, Ọọ̀nirìṣà,Ògúnwùsì ṣàmúlò ìṣẹ̀ṣe orò bi ọ̀nà àbáyọ

Nítorí ẹbọra kòrónà, Ọọ̀nirìṣà,Ògúnwùsì ṣàmúlò ìṣẹ̀ṣe orò bi ọ̀nà àbáyọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbogbo àgbáyé ti ń dààmú lórí àrùn yìí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù báyìí láìsí ọ̀nà àbáyọ kan tó dán mọ́rán.

Àrùn kòrónà ti sọ ara rẹ̀ di ẹrujẹjẹ ní gbogbo ilẹ̀kílẹ̀, ẹbọra tí ń se gbogbo ayé mọ́lé porogodo.

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní n tó bá rúni lójú, àá bi Ilẹ̀ léèrè.

Èyí ló dífá fún Ọọni ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ti ké sáwọn alálẹ̀ ilẹ̀ yìí láti lé àrùn kòrónà tó gbòde kan báyìí wọgbó.

Ìdí nìyí tí Kábíyèysí Ọọni fi kéde pé kí gbogbo àwọn olùgbé ìlú Ifẹ̀ ó wà nínú Ilé wọn nítorí orò fẹ́ jáde láti fọ ìlú mọ́ lọ́wọ́ àrùn kòrónà.

Àtẹ̀jáde kan tí Ọọni fi síta láti ọwọ́ Olóyè Ọyalami Awoyọde ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ yọjú síta nítorí bí ẹnikẹ́ni bá fojú ba orò yìí, orò náà yóó gbe ni o.

Ọọni Ilé Ifẹ̀ ṣàlàyé nínú àtẹjáde náà pé, lára àwọn ibi tí orò náà yóó gbà kọjá ni iwara ilode, oke atan, iloro, aganhun, arubidi, moremi, ondo road, olurin, omi okun, iyekere, oroto, itaagbon, oke ayetoro, oke soda, otutu,

ajamopo, ita sun, lokore, odoiwara, olumogbe, ijio, ojafe, edena, igbo agbo, obaloogun, onpetu, oduduwa college road, akiile, ilare, saabo, iremo, okerewe, obalejugbe, garage isale, mokuro road, ojaja, ogbingbin, okejan,

iredumi, lagere, fajuyi, gbodo, ita olopo, isale agbara, ogbon agbara, ogbon oya, akui, obalufon, itakogun, oriyangi, ehindi, omisore,olurin, pediro, okemorisa, àtàwọn ibò míì.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …