Home ÀKỌ̀TUN Gómìnà Makinde ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń gbèrò lórí sísọ ìbòjú wíwọ̀ dí dandan fún aráàlú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 1, 2020

Gómìnà Makinde ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń gbèrò lórí sísọ ìbòjú wíwọ̀ dí dandan fún aráàlú

Gómìnà Makinde ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ń gbèrò lórí sísọ ìbòjú wíwọ̀ dí dandan fún aráàlú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà Ṣèyí Mákindé ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sọ pé ó ṣeéṣe kí Ìjọba pàṣẹ lílò ìbòjú ní tipátipá fún àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà bí wọ́n bá fẹ́ jáde lọ ṣe ohunkóhun.

Gómìnà Mákindé sọrọ yii lásìkò tó ń dáhùn ìbéèrè lórí iléeṣẹ́ Redio kan ní ìlú Ìbàdàn ní Òwúrọ ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Gómìnà Mákindé kéde pé òun ti kó àrùn náà ní ọjọ́ Ajé.

Ó ní òun ti bẹ̀rẹ̀ sí níí rọ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ìsàkóso ètò ìgbógun ti àrùn náà nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò.

Gómìnà Mákindé ní òun ríi pé ìgbésẹ̀ kíkàn án nípá fún gbogbo èèyàn tó bá fẹ́ jáde láti máa lo ohun èlò ìdáàbòbò ìbòjú ni ijọba orilẹede Czech Republic lò láti fi kojú àrùn náà, tí òun sì ríi pé ó ń jẹ́ fún wọn bí i idán.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…