Home ÀKỌ̀TUN Ènìyàn mẹ́sàn án l’Ọ́ṣun, méjì l’Edo, Ẹ̀yọkan l’Ékìtì kó Coronavirus
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - April 1, 2020

Ènìyàn mẹ́sàn án l’Ọ́ṣun, méjì l’Edo, Ẹ̀yọkan l’Ékìtì kó Coronavirus

Ènìyàn mẹ́sàn án l’Ọ́ṣun, méjì l’Edo, Ẹ̀yọkan l’Ékìtì kó Coronavirus

Fẹ́mi Akínṣọlá

Hun! Kò tó nǹkan, kò tó nǹkan, ó mà fẹ́ má a dòòyì kọ́ni . À fí kí á túbọ̀ gbóhùn ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run Elédùwà o, pẹ̀lú bí àrùn apinni léèmí ọ̀hún ṣe n ràn mọ̀ọ̀,bí àyẹ̀wò se tún
ti fihàn pé èèyàn méjìlá míràn tún tí lùgbàdì àrùn apinni léèmí Coronavirus báyìí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àtẹ̀jáde kan eléyìí tí àjọ tó ń rí sí ìgbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi síta lójú òpó twitter wọn ṣàlàyé pé, èèyàn mẹ́sàn nínú àwọn tí àyẹwò sẹ̀sẹ̀ fi hàn náà ló wá láti ìpínlẹ̀ Ọṣun, méjì wá ní ìpínlẹ̀ Edo, nígbà tí ọ̀kan tó kù sì wá láti Ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Èyí ti sún iye àwọn tó ní àrùn yìí síwájú di mọ́kànléláàdọ́jọ, 151.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…