Èèyàn mẹ́sàn án míràn tún ní Coronavirus nípìnlẹ́ Èkó, ó di èèyàn 111 tó níi ní Nàìjíríà
Èèyàn mẹ́sàn án míràn tún ní Coronavirus nípìnlẹ́ Èkó, ó di èèyàn 111 tó níi ní Nàìjíríà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àbájáde ìgbìmọ̀ kan tí ilé ẹkọ Fásitì Ìbàdàn gbé kalẹ̀ lórí àti wòye bí nǹkan se n lọ lórí àrùn apinni ní èémí coronavirus tí wọ́n fèèbo pé ní “Covid 19” tí ṣọ pé a fí kí a múra gírí kí a sì gbọ́ ìkìlọ̀ , bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pẹ̀lú àfihàn àkọsílẹ̀ yìí, nígbà tí yóó bá fí di ọjọ́ Ẹtì ọjọ kẹta oṣù kẹrin 3/4/2020 ọsẹ tí a mú yìí,o súnmọ́ kí òǹkà àwọn ọmọ orílẹ̀ yìí yóó mú ó tí yí bìrìpé wọ ọ̀ọ́dúnrún. Ní báyìí, ènìyàn mẹ́rìnlà míràn tún ti ní àrùn coronavirus ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Àjọ tó ń rí sí ìdènà àti amójútó àjàkálẹ̀ àrùn, NCDC ló fi Ìkéde náà síta lálẹ́ ọjọ́ Àìkú lójú òpó Twitter rẹ̀.
Mẹ́sàn án nínú àwọn èèyàn ọ̀hún wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, tí àwọn márùn ún tó kù sì wà ní Abuja.
Níbi ọ̀rọ̀ dé dúró báyìí, èèyàn mọ́kànléláàdọ́fà (111) ló ti lùgbàdi àrùn náà lórílẹ̀-èdè yìí, tí ẹnìkan sì ti jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…