Home ÀKỌ̀TUN Mínísítà ìlera tí jẹ́ àbọ̀ fún Ààrẹ Buhari lórí àrùn apinni ní èémí Coronavirus
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 29, 2020

Mínísítà ìlera tí jẹ́ àbọ̀ fún Ààrẹ Buhari lórí àrùn apinni ní èémí Coronavirus

Mínísítà ìlera tí jẹ́ àbọ̀ fún Ààrẹ Buhari lórí àrùn apinni ní èémí Coronavirus

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari ti fojú hàn ní ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà tí awuyewuye lórí ibi tó ṣá pamọ́ sí ti bẹ̀rẹ̀ lójú òpó ayélujára ní Nàìjíríà pẹ̀lú hashtag #BuhariResign.

Ààrẹ Buhari gbàlejò Mínísítà fétò ìlera àti ọ̀gá àgbà àjọ tó ń kojú àìsàn ní Nàìjíríà,NCDC nílé Ìjọba lọ́sàn án ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Nínú àwọn fọ́nrán fídíò àti àwòrán tí iléeṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà fi síta, a rí i tí Ààrẹ Buhari jókòó jìnà sí Mínísítà Osagie Ehanire àti Dókítà Chikwe Ihekweazu.

Gẹ́gẹ́ bí àkọlé àwọn àwòrán náà ti ṣe ṣàlàyé, iléeṣẹ́ Ààrẹ ní àwọn méjéèjì wá jábọ̀ fún Ààrẹ bí nǹkan ti ṣe ń lọ pẹ̀lú kíkojú àjàkálẹ̀ Coronavirus.

Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí tí ìròyìn ti lu síta pé olórí àwọn òṣìṣẹ́ fún Ààrẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari náà ti ní àrùn Coronavirus ni àwọn èèyàn ti ní àwọn kò kó fìrí Ààrẹ Muhammadu Buhari mọ́.

Lójú òpó Twitter, àwọn èèyàn ń bèèrè pé níbo ni Ààrẹ wà táwọn kan sì ní ó ti lọ gba ìtọ́jú lẹ́yìn odi.

Kété tí fọ́nrán fídíò àti àwòrán Ààrẹ jáde lójú òpó Twitter làwọn ọmọ Nàìjíríà ti ń sọ èrò ọkàn wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…