Home ÀKỌ̀TUN Buhari pàsẹ ìséde ní Eko, Abuja àti Ogun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 29, 2020

Buhari pàsẹ ìséde ní Eko, Abuja àti Ogun

Buhari pàsẹ títì pa Eko, Abuja àti Ogun
Ìròyìn láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Arun kogboogun (coronavirus) to fe di toro fon kale yii lo mu ki Aare Mohammadu Buhari pase yii nigba ti o n ba awa ara ilu soro ni aago meje irole oni.
Aare ni, “irorun eku ni irorun eye”. O ni alaafia awon ara ilu lo je oun logun, eyi lo maa mu ki awon ipinle ti arun buruku naa ti gbile si wa ni titi pa patapata lati aago mokanla ale ola ogbon ojo, osu keta ti a wa yii. Aare ni titi pa naa si maa gba ose meji gbako ki ijoba to tun mo odo miiran ti o maa da orunla si.
Aare te siwaju pe awon ti arun naa ti wo lara po ni ipinle Eko ju gbogbo ipinle to ku lo ni eyi to je ki ijoba tete fi owo ranse si won. O ni leyin ipinle Eko lo kan ipinle Abuja ninu ipinle ti arun naa po si, eyi naa maa fa titi pa oluulu naa. O ni ipinle Ogun lo paala pelu ipinle Eko ti arun naa rogun si. O ni eegun si ti wo inu eran bi eran naa se wo inu eegun, o ni ipinle ogun tun paala pelu orileede Benin. O ni gbogbo eyi lo fa titi pa ipinle Ogun.
Pelu bii gbogbo nnkan se le to naa, o ni aaye si wa fun awon eleto ilera, oniroyin, awon elepo petiro, ajo panapana, ajo olomi, onina ijoba ati awon osise ko-see-ma-ni miiran to ba ni eri to daju.
Aare ni igbese yii waye latari bi arun buruku naa se n ja ni awon orileede bii Italy, China ati USA. O ni oro oloro lo si dara lati fi se arikogbon. O ni awon eniyan awon ipinle yii ni lati fi idi mole fun ose meji naa lati le tete da ibi ti arun naa ku si mo.
Aare Buhari salaye pe arun naa ko lapa, bee ni ko lese, o ni awa eniyan ni a bere si ni gbee kiri ni eyi to si lewu gidi fun awon ti arun naa ko tii de odo won. O ni, o ti han kedere pelu ayewo awon onimo ilera pe arun ajoji ni arun naa, bee si ni awon to ti irinajo oke okun de ni won ko arun naa wole.
Aare beere fun iranlowo awon ara ilu lati gbogun ti ajakale arun naa. Aare ko tun sai femi imoore han si awon ti Olorun bu kun ti won ti kopa ninu idasi owo fun igbogun ti aisan naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…