Home ÀKỌ̀TUN Àwọn mínísítà ní Náíjíríà fi ìdá 50% owó osù wọn fún ìdẹ́kun Coronavirus
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 29, 2020

Àwọn mínísítà ní Náíjíríà fi ìdá 50% owó osù wọn fún ìdẹ́kun Coronavirus

Àwọn mínísítà ní Náíjíríà fi ìdá 50% owó osù wọn fún ìdẹ́kun Coronavirus

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn mínísítà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti sèlérí láti fi ìdá àádọ́ta lára owó oṣù kẹta wọn ṣe ìrànwọ́ fún Ìjọba Nàìjíríà láti kojú àrùn Coronavirus.

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Muhammadu Buhari, Bashir Ahmad ló fi léde lójú òpó Twitter rẹ̀ ní Ọjọ́ Sátidé pé inú atẹjade tí Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ìròyìn, Alhaji Lai Muhammed fi léde ni ìròyìn náà wà.

Ahmad ní àwọn mínísítà mẹtàlélọ́gọ́rin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló setán láti gbé ìgbésẹ̀ tí yóó mú àtúnṣe bá gbígbógun ti àjàkálẹ̀ àrùn náà tó ń jà nílẹ̀ ràn ìn.

Ìròyìn sọ wí pé àwọn mínísítà náà gbé ìgbésẹ̀ náà láti ṣe kóríyá fún ìgbésẹ̀ Ìjọba láti kojú àrùn náà.

Bákan náà ni àwọn mínísítà náà gbóríyìn fún Ààrẹ Muhammadu Buhari fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe láti gbógun ti àrùn náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé Ọrẹ Òtítọ́jù Àjọ tó ń gbó…