Home ÀKỌ̀TUN Ààrẹ f’òfin de ìrìnà ní Eko,Ogun ati Abuja fọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 29, 2020

Ààrẹ f’òfin de ìrìnà ní Eko,Ogun ati Abuja fọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko

Ààrẹ f’òfin de ìrìnà ní Eko,Ogun ati Abuja fọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ tí a bá gbọ́ lẹ́nu arúgbó onísàngó, kò sí tàbí ṣùgbọ́n, ẹnu Imọlẹ̀ ló tí jáde o.

Bàbá ò ṣọ̀rọ̀ , bàbá ò ṣọ̀rọ̀, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,Muhammadu Buhari ti kéde pé kò ní sí wíwọlé-wọde ọkọ̀ láàrin ìpínlẹ̀ Eko,Ogun ati Abuja fún ọjọ́ mẹ́rìnlà gbáko.

Ìṣéde yìí tó pàṣẹ rẹ̀ yóó bẹ̀rẹ̀ láago mọ́kànlá ọjọ́ Ajé tí ṣe ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹta.

Nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lórí àjàkálẹ̀ àrùn Corona Virus ló ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ Coronavirus lórílẹ̀ yìí.

Àwọn ìgbésẹ̀ mí ì tó kéde, Ààrẹ ní gbogbo àwọn èèyàn agbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ yí kàn ni kí wọ́n má se jáde rárá.

Gbogbo káràkátà àti iléeṣẹ́ pátá ni yóó wà ní títí pa. Kí ohun gbogbo o kọ́kọ́ di wápe. Látàrí àti le mọ ibi tí nǹkan de dúró àti ìgbésẹ̀ tó kàn.

Ó fi kún un pé ọ̀rọ̀ yí kò ní kan àwọn oníṣẹ́ ìlera àti àwọn tí ó ń pèsè irinṣẹ́ ìlera.

Àmọ́ akọ̀ròyìn kankan tí yóó ba jáde síta ní láti fi ẹ̀rí hàn pé òun kò lè ṣe iṣẹ́ láti Ilé, àfi ní ọ́fíìsì rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìka…