Home ÀKỌ̀TUN Ariwo kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Akure ní àwọn ènìyàn fi bọnu!
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 28, 2020

Ariwo kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Akure ní àwọn ènìyàn fi bọnu!

Ariwo kí ló ń ṣẹlẹ̀ ní Akure ní àwọn ènìyàn fi bọnu!

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó kéré tán Ilé méjì tí àwọn ènìyàn ń gbé, ilé ẹkọ ati Ilé ìjọsìn ló wó ní ìlú Akure lẹ́yìn tí ìbúgbàmù dún ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ondo, Tee-Leo Ikoro ló fi ọ̀rọ̀ náà léde fún akọ̀ròyìn.

Tee-Leo Ikoro ní iléeṣẹ́ tó ń ṣe àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣe ojú ọ̀nà ló fa ìbúgbàmù náà, àmọ́ kìí sẹ àdó olóró.

Ó ní ohun èlò ìbúgbàmù náà ya ọ̀nà tó wà ní òpópónà tó lọ sí pápákọ̀ òfurufú ní ìpínlẹ̀ náà jẹ́ àti Ilé méjì tó wà ní ẹ̀bá ọ̀nà ní agbègbè Eleyowo ní ìpínlẹ̀ náà.

Ìròyìn fi léde pé àwọn ènìyàn tó wà ní agbègbè náà fi ara pa, kí ó tó di wí pé ìrànwọ́ dé.

Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ondo ní kò sí ẹ̀mí tó sọnù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n awakọ̀ náà farapa tó sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní ilé ìwòsàn ní ìpínlẹ̀ náà.

Àmọ́, Oluyemi Fasipe lójú òpó Twitter rẹ̀ sọ wí pé ìbúgbàmù náà ba àwọn ilé àti dúkìá jẹ́, tó fi mọ́ Ilé epo tó wà ní agbègbè Ogbẹsẹ.

Bákan náà ni wọ́n ní ìbúgbàmù náà la ọ̀nà náà sí méjì, tó fi mọ́ Ilé ìjọsìn ní agbègbè náà.

Arábìnrin Temidayo ní ojú òpó Twitter rẹ̀ sọ wí pé ìbúgbàmù náà ba nǹkan jẹ́ nínú Ilé wọn.àá áà

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …