Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀nì jẹ ọkùnrin Rwanda kan tí kò pa òfin kónílé-ó-gbélé nítorí coronavirus mọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 27, 2020

Ọ̀nì jẹ ọkùnrin Rwanda kan tí kò pa òfin kónílé-ó-gbélé nítorí coronavirus mọ́

Ọ̀ọ̀ni jẹ ọkùnrin Rwanda kan tí kò pa òfin kónílé-ó-gbélé nítorí coronavirus mọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ìgbọràn sàn ju ẹbọ rírun ni àwọn àgbà wí. Bẹ́ẹ̀ ohunkóhun ló sì leè tẹ̀yìn àìgbọrọ̀ yọ.
Ọkùnrin kan tó kọ̀ láti tẹ̀lé òfin kónílé ó gbélé tí Ìjọba orílẹ̀-èdè Rwanda fi síta nítorí ìtànkálẹ̀ àrùn coronavirus ti sàgbákò ikú ójijì.

Ọkùnrin náà fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ sí odò láti pa ẹja, ṣùgbọ́n ọ̀ọ̀nì sọ ọkùnrin náà di oúnjẹ.

Olórí agbègbè Gúúsù Kamonyi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, Alice Kayitesi sọ fún akọ̀ròyìn pé Òwúrọ Ọjọ́bọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ àgbọ́gbárímú náà ṣẹlẹ̀ ní odò Nyabarongo.

“Ó kọ̀ láti tẹ̀lé òfin Ìjọba pé ki olúkúlùkù jókòó sílé rẹ̀, ó wà lára àwọn ènìyàn díẹ̀ tí kò pa òfin náà mọ́, láti dènà ìtànkálẹ̀ coronavirus.”

Ọjọ́ àìkú tó kọjá ni àwọn aláṣẹ ní Rwanda pàṣẹ pé kí gbogbo nǹkan ó dáwọ́ dúró, nítorí bí àwọn tó ní àrùn náà ṣe ń pọ̀ sí i.

Ogójì ènìyàn ló ti ní coronavirus ni Rwanda.

Bí Ìjọba ṣe f’òfin de ètò ọrọ̀ ajé ti ṣe àkóbá ńlá fún ọpọ ènìyàn tí kò rọ́wọ́ họrí nílù ú náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…