Home ÀKỌ̀TUN Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí coronavirus
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 26, 2020

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí coronavirus

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kéde pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí coronavirus

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbogbo ọ̀nà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ àkóso Gómìnà Ṣèyí Mákindé ń sán láti sẹ́bùrú àrùn apinni ní mímí èèmii coronavirus, bí ó tún ti gbé ìgbésẹ̀ Ọlọ́gbọ́n láti kójú ìtànkálẹ̀ àrùn yìí.Ní báyìí, Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ti ìlẹ̀kùn iléeṣẹ́ Ìjọba pa fún ọ̀sẹ̀ méjì gbáko nítorí ìtànkálẹ̀ àrùn coronavirus nípìńlẹ̀ náà.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà, Ṣèyí Mákindé ló kéde bẹ́ẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lójú òpó Twitter rẹ̀ lọ́jọ́rú.

Àṣẹ náà yóó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtadínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta, ọdún 2020.

Mákindé sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ wọ́n jẹ́ kòseémánì nìkan ni yóó ma lọ sí ibi iṣẹ́ wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn ló …