Home ÀKỌ̀TUN Ha! Mo ṣe ìpàdé pẹ̀lú ẹni tó ní Coronavirus- Gómìnà Akérédolú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 26, 2020

Ha! Mo ṣe ìpàdé pẹ̀lú ẹni tó ní Coronavirus- Gómìnà Akérédolú

Ha! Mo ṣe ìpàdé pẹ̀lú ẹni tó ní Coronavirus- Gómìnà Akérédolú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ kòrónáfairọ̀ọ̀sì yìí ti wá di bá a se n yọ so, bẹ́ẹ̀ náà là ń yọ gbọ́, bí ó ṣé di pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ Gómìnà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló ti jáde láti lọ ṣe àyẹ̀wò bóyá wọ́n ní àrùn Coronavirus láti ìgbà tí àjàkálẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀.G Gómìnà Akérédolú papà á kò gbẹ́yìn.
Èyí kò ṣẹ̀yin àwọn ènìyàn tó bu ẹnu àtẹ́ lu Gómìnà náà, Akérédolú pé kò lọ ṣe àyẹ̀wò ara rẹ̀ nítorí ó ṣe ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú ẹni tí iléeṣẹ́ ètò ìlera sọ wí pé ó ní àrùn Coronavirus.

Akérédolú nínú àtẹjáde tó fi léde sọ pé, òun tí ṣetán láti ṣe àyẹ̀wò bóyá òun ní Coronavirus.
Ó ní òun gbé ìgbésẹ̀ náà nítorí ẹni tí òun bá ṣe ìpàdé ti ní àrùn Coronavirus.
Ó fikún un pé òun yóó jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ èsì àyẹwò Coronavirus náà láìpẹ́.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo wà ní ìpàdé ní ìlú Abuja pẹ̀lú àwọn Gómìnà tó wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ní Báyìí, ọ̀kan lára àwọn Gómìnà náà ti ní àrùn Coronavirus náà.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì àti ti ìpínlẹ̀ Niger tó wà ní ibi ìpàdé náà ti ṣé ara wọn mọ́ Ilé báyìí, tí wọ́n sì ti lọ ṣe àyẹ̀wò ara wọn.

Àmọ́ àwọn ènìyàn sọ wí pé Gómìnà Akérédolú kọ̀ láti ṣé ara rẹ̀ mọ́lé, tí ó sì ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ondo, Adie Undie ní Ọjọ́rú, ọ̀sẹ̀ yìí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀…