Home ÀKỌ̀TUN Olùkó̩ni Arteta ti rí ìwòsàn

Olùkó̩ni Arteta ti rí ìwòsàn

Olùkó̩ni Arteta ti rí ìwòsàn

Lati owo Akinwale Taophic

Olukoni fun egbe agbaboolu Arsenal ni orileede England, eni ti okiki kan kaakiri ni bi ose meji seyin wi pe o ti ni aisan Coronavirus, Mikel Arteta, ni o ti je ki o di mimo ni owuro ojo aje ti o koja yi wi pe ara oun ti ya patapata bayii.

Arteta, eni ti o fura si ara re ni ojo kejila osu keta odun ti a wa yi, leyin igba ti o gbo wi pe eni ti o ni egbe agbaboolu Olympiakos, Evangelos Marinakis, ti ni arun naa, ti oun gan-an-gan si mo daju wi pe nnkan pa awon po nigba ti won wa ba awon gba boolu ninu idije Uefa Europa league. Awon eleto ilera se ayewo fun, won si ri wi pe o ti ni arun naa, leyin naa ni won pa lase fun gbogbo awon agbaboolu Arsenal lati wa ni igbele lai jade rara fun ojo merinla, ti won si bere itoju fun olukoni naa lesekese ki o to ri iwosan gba leyin o reyin.

Ojo isegun ti o koja lo yi ni o ye ki awon agbaboolu Arsenal o pada si papa isere fun ibere igbaradi won sugbon ti awon alokoso iko naa tun da oro naa to ti won si kede wi pe ki won o ma wole mo, ki o lukuluku won joko si ile won lati maa ba lugbade arun naa titi di ojo miran ti won yio pada kede.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…