Home ÀKỌ̀TUN Àjo̩ UEFA ti sún ìdíje Champions league àti EUROPA síwájú

Àjo̩ UEFA ti sún ìdíje Champions league àti EUROPA síwájú

Àjo̩ UEFA ti sún ìdíje Champions league àti EUROPA síwájú

Lati owo Akinwale Taophic

Leyin ipade oro siso lati ori ero amohun-maworan ayelujara eyi ti ajo UEFA ati gbogbo awon ti oro idije Uefa Champions league ati Europa League gberu se ni Owuro ojo aje ti o koja lo yi, ninu eyi ti olori ajo naa, Alekzander Ceferin, dari, won je ki o di mimo wi pe ko si oun kankan ti won le se si oro awon idije bi Uefa Champions league, Europa league ati Uefa Champion league ti awon obinrin ti ireti wa tele wi pe o ye ki awon asekagba won waye ni ipari osu karun-un odun yi, ju ki won o sun won si iwaju di ojo miran ti ko ni gbedeke rara, titi di igba ti gbogbo oro aisan Coronavirus eyi ti o so gbogbo orileede agbaye ati awon eniyan sinu hilahilo lati bi osu meji seyin, yio fi di afiseyin ti egungun n fi aso.

Arun naa ti o bere ni Wuhan ni orileede China, ti gba emi opolopo eniyan kaakiri agbaye. Ni bayii, arun naa ti di gbajugbaja kaakiri gbogbo orileede, ti ko si fee si orileede kankan lagbaye ti ko ti i de sugbon orileede China ati Italy ni o ti se ose julo. Opolopo awon agbaboolu ni won ti fi ara kasa, bakan naa ni awon olukoni ati awon alamojuto egbe agbaboolu kogbeyin rara ninu ose ti arun naa n se. O le to bee ge ti ohun gbogbo fi polukumusu ti gbogbo orileede si n pase ki o ma so ere Idaraya tabi ipejopo kankan ni ibikibi. Gbogbo idije keekeke ati awon ti won Ni ikimi kaakiri agbaye ni won ti da duro, ti ajo Uefa si lora die lati soro isun siwaju awon idije Uefa sita.

E je ki a ran arawa leti wi pe abala eleni merindinlogun ni won gba idije uefa champions league de, ti won si ti gba ifigagbaga merin ninu mejo ki o to di wi pe won ko le tesiwaju latari arun yi. Atletico Madrid ti yan yo leyin ti won da yerupe si Gaari Liverpool, PSG naa yan yo pelu bi won se bori Burussia Dortmund, Atalanta bori Valencia, nigba ti RB Leipzig naa ran olukoni Mourinho ati awon agbaboolu re ninu iko Totteham pade sile.

Ni bayii, ifigagbaga merin ti o ku ni abala eleni merindinlogun ninu idije Uefa Champions league ni wonyi: Manchester City Vs Real Madrid, Juventus Vs Olympic Lyon, Barcelona Fc Vs Napoli ati Bayern Munich Vs Chelsea.

Bakan naa, awon ajo ti won n se kokaari liigi orileede Spain-Laliga, ti je ki o di mimo wi pe, won ti fi enu ko lati sun liigi naa siwaju di ojo miran ojo ire. Won so wipe igbakugba ti Ijoba orileede Spain ba to so wipe ki ere Idaraya o bere pada ni orileede naa ni liigi naa yio to bere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…