Wo àwọn irọ́ tí wọ́n ń pa fún ọ nípa àrùn Coronavirus
Wo àwọn irọ́ tí wọ́n ń pa fún ọ nípa àrùn Coronavirus
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé o yẹ kí ẹ̀dá wádìí ohun gbogbo dájú kí ó lè di èyí tíí se òdodo mú.
A ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìwòsàn tí àwọn ènìyàn ti ń polongo kiri, àti nǹkan tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ nípa wọn.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìròyìn ló ti bọ́ sí gboro ayé pé jíjẹ gálíìkì, tí Yorùbá ń pè ní ata’lè láti dèna àrùn ti gbalé-gboko lórí ayélujára Facebook.
Lọ́pọ̀ ìgbà irú àwọn ìwòsàn báyìí kò l”ewu, ṣùgbọ́n wọ́n tún le fa wàhálà sí àgọ́ ara.
Ọsẹ ìpawọ́ apa kòkòrò (Hand sanitiser) tí a ṣe nílé
Ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ sọ pé àwọn kò gbàgbọ́ pé ẹnìkan le ṣe ìpawọ́ apa kòkòrò tó leè dènà àrùn náà l’ábẹ́ẹlẹ́.
Ọ̀pọ̀ wọn sì ni kò dára fún ara ènìyàn.
Mímu omi ní ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún.
Inú ọ̀pá tó ń gbé èémí ni àrùn bí coronavirus ń gbà wọ inú ara. Díẹ̀ lára wọn sì le wọ ẹnu rẹ, ṣùgbọ́n omi mímu léra-léra kò ní- ín dènà rẹ̀ẹ̀ pé kó o má ní- in.
Ooru àti yíyàgò fún ìpanu ‘ice cream’
Ìròyìn kan tó ti gbalé-gboko káàkiri àgbáyé – tí wọ́n sì sọ pé ó wá láti ọwọ́ àjọ tó ń mójútó ìlera àwọn ọmọdé l’ágbàáyé, Unicef -sọ pé mímu omi tó gbóná, àti dídúró sínú òòrùn , tó fi mọ́ yíyàgò fun ‘ice cream’ le pa arun naa.
Ṣùgbọ́n, òṣìṣẹ́ àjọ Unicef kan, Charlotte Gornitzka sọ pé irọ́ ni Ìròyìn náà.
Nítorí náà, sísá ara rẹ sínú òòrùn, tàbí mu omi gbígbóná, àti wíwẹ̀ pẹ̀lú omi gbígbóná kò le ràn ọ́ lọ́wọ́.
Tí àrùn náà bá ti wọ ara, kò sí ọ̀nà láti pa á.
Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo
Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …