Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀nà Jìbìtì
ÀKỌ̀TUN - ÀRÒJINLẸ̀ - March 18, 2020

Ọ̀nà Jìbìtì

Bi ara ipede Radio Naigeria O.Y.O ni aye atijo, won ni, “Ifunra loogun agba, pasa ko funra, o ja sina, aja ko funra, aja jin, ti onile naa ko ba funra, ole ni yoo ko lo”. Eyi ni o difa fun gbogbo awa ti a maa n gbe moto lo si ibi inawo.
Ara iwa jibiti ibe ni ki awon kan lo ba adari eto ti gbogbo eniyan mo si M.C. Won a ni ki o polongo nomba moto jade, ki eni to nii le wa tun wa si ibi to dara.
Igba ti eni naa ba de ibe lo maa dede ri awon kan ti won ti go dee pelu ibon. Won si maa ni ki o ko gbogbo owo ati awon nnkan miiran to ba lowo lori fun awon loju ese.
Opo to ba se agidi maa n sabaa fara gba ogbe ti won ko ba ba isele naa lo.
Iwe IROYIN OWURO wa n gba wa niyanju pe ti iru ikede bee ba sele, ki onimoto ma tete lo, ti o ba si lo ki o ma se da lo. E ma se je ki a dabii “f’Olorunso to n fokun ogede gope”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Ilé ẹjọ́ tú el-zakzaky àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ Fẹ́mi Akínṣọlá Ajá tó relé ẹkùn tó bọ̀,ó tọ́ kí…