Home ÀKỌ̀TUN Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìyọnípò Oshiomole gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 17, 2020

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìyọnípò Oshiomole gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìyọnípò Oshiomole gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ fini lògbòlògbò yini nù lọ̀rọ̀ ọ Alága gbogbo gbòò ẹgbẹ́ òsèlú APC dà báyìí o, bí Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ìlú Abuja ti ní Adams Oshiomhole sì ni Alága gbogbo gbòò fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà, tí adájọ́ Abubaka Datti Yahaya kó sòdí wọ́gilé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja dá Ṣaájú, léyìí tó yọ Oshiomole nípò gẹ́gẹ́ bí Alága ẹgbẹ́ ọ̀hún.

Ṣaájú ni oshiomole ti rọ ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà láti gbé ìdájọ́ ìyọnípò rẹ̀ náà tì ṣí ẹ̀gbẹ́ kan.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀, adájọ́ náà kìlọ̀ fún àwọn tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún kàn láti má gbé ìgbésẹ̀ tí yóó tako ìdájọ́ tó gbé kalẹ̀.

Lẹ́yìn náà ló rọ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú láti máa yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàrin wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá dípò kí wọ́n máa yọ ilé ẹjọ́ lẹ́nu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…