Home ÀKỌ̀TUN Ighalo so̩ àwo̩n e̩lé̩gàn di òpùró̩
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - Sports - March 16, 2020

Ighalo so̩ àwo̩n e̩lé̩gàn di òpùró̩

Ighalo so̩ àwo̩n e̩lé̩gàn di òpùró̩
Iroyin lati owo Akinwale Taophic

Atamatase fun orileede wa Nigeria nigba kan ri, eni ti o se gudugudu meje ati yaaya mefa ninu idije ife eye ile adulawo ti won gba keyin ni orileede Egypt ni inu odun 2019 ti o koja, Odion Jude Ighalo, ti pa enu awon elegan mo pelu bi o se n gba ami ayo wole fun iko Manchester United ti o sese darapo mo pelu adehun alayalo ni orileede England, ti o si n se daradara nibe.

Opolopo awon ololufe ere boolu alafesegba ajaaja awon ti won n tele iko Manchester United ninu liigi ile Geesi ni o ba lojiji nigba ti iroyin sadeede Jade wi pe oro ti wo laarin agbenuso fun Ighalo ati egbe agbaboolu naa, ti agbaboolu naa si gba lati se gbogbo ohun ti o wa ni ikapa re lati ri wi pe oro naa bo si. Se won ni ete Awo Ni erin Ogberi, ha-hin, Ighalo khe ! Se iru re ni a n so ni ? Tandu Martial ni a so wi pe ko mo ijo jo, ewo tun ni Tandu-Tandu ti Ighalo? Ni asiko ti Man U wa yi, awon wo lo gba won lamoran? Iru igbese radarada wo ni eleyii, nigba ti opolopo awon atamatase ti won gbonje-fegbe wa kaakiri agbaye ! Orisirisi oro ni opolopo awon alaropin eniyan yi n so kiri ninu iwe iroyin ati ori ero ayelukara kaakiri sugbon won gbagbe wi pe “Riro ni teniyan sugbon sise Ni t’Olorun Oba”

Opolopo oro kobakungbe yii ni won so de etigbo Ighalo, ko fesi rara koda ko se bi eni ti o gbo. Eyi ti o baa lokanje ju ni ti awon omo orileede Nigeria ti awon na n bu enu ate lu wipe “Ohun rere kankan ko le ti Isireli re Jade” ! Bee tun ni opolopo awon agbaboolu feyinti kuro ninu iko Man U bi Rio Ferdinand ati Garry Neville naa bu enu ate lu omokunrin atamatase yii.

Ighalo ko je ki gbogbo eleyi o ko irewesi okan ba oun rara, o gbaju mo ohun ti o wa se ninu iko Man U, o si ni afojusun lati pa enu gbogbo awon elegan mo. Ni kete ti o wo orileede England, won ko je ki o darapo mo awon akegbe re lati gbaradi rara nitori ibi ti o ti n bo, orileede China, ibi ti aisan coronavirus ti bere ti o si gbile gan, o n da igbaradi se nibi kan ti o sun mo ibudo igbaradi iko Manchester City ni.

Leyin opolopo ayewo ilera, o darapo mo awon akegbe re yoku, ohun gbogbo si bere ni perehu. Ninu ifigagbaga re akoko ni apere ti n fi oju han diedie wi pe o seese ki ona ma gba gbogbo ibi ti awon elegan re fojusi lo rara nitori die bayii loku ki o gba ami ayo wole koju egbe agbaboolu Chelsea ni ojo naa laarin iseju perete ti won gbe wole .

Lati eyin igba naa ni o ti n da bi Edun ti o si n ro bi Owe ninu iko naa. Ni bayii, pelu ifigagbaga ti o gba koju iko LASK lati orileede Austria ni Papa isere Linzer Ni ojobo ose ti o koja lo yi ninu idije Europa League nibi ti o ti gba ami ayo akoko wole, o ti di ifigagbaga meta ti o ti ba won bere, o si ti gba ami ayo merin wole. Man U bori LASK pelu ami ayo marun-un si odo (5-0) ninu eyi ti Daniel James, Juan Mata, Mason Greenwood ati Andreas Pereira ti gba ami ayo kookan wole leyin ti Ighalo.

Idarapo Ighalo pelu egbe agbaboolu Manchester United ko orire ba won gidi gan an ni nitori wi pe won ko ti padanu ifigagbaga kankan ninu mokanla ti won ti gba bayii ninu gbogbo idije patapata.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…