Home ÀKỌ̀TUN Ọ̀ràn dé! Alárùn coronavirus di méjì ní Nàìjíríà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 9, 2020

Ọ̀ràn dé! Alárùn coronavirus di méjì ní Nàìjíríà

Lara ayewo ti ijoba apapo ati awon ajo NCDC (Nigeria Centre for Disease Control) n se pelu awon ti won ba arakunrin ara orileede Italy wo baalu ati oko po. Won n se ayewo yii naa pelu awon ti won jo se ipade ni ilu Ewekoro to wa ni ipinle Ogun.
Ileese Lafarge Cement Plant Plc ni ipade naa ti waye. Eyi lo mu ki ijoba apapo ati ti ipinle Ogun pelu Eko pa imo po lati maa se ayewo gbogbo awon to ni asepo pelu arakunrin yii lati ojo keedogbon osu keji odun yii.
Dokita Osagie Ehanire jeri si oro naa pe awon ti ri elomiran to ko kokoro naa lati odo okunrin naa.
Dokita yii si tun fi gbogbo omo Naijiria lokan bale pe ko si ewu Kankan, ki onikaluku maa lo si ibi ise oojo re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù Ọrẹ Òtítọ́jù Àwọn …