Home ÀKỌ̀TUN Ìdá àadọrùn (90%) nínú àwọn olówó Nàìjíríà ló ń lọ ilé babaláwo- Mr Latin
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 6, 2020

Ìdá àadọrùn (90%) nínú àwọn olówó Nàìjíríà ló ń lọ ilé babaláwo- Mr Latin

Ìdá àadọrùn (90%) nínú àwọn olówó Nàìjíríà ló ń lọ ilé babaláwo- Mr Latin

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní arínú róde kan,kìí jẹhun àwùjọ ọ tì.
Àgbà òṣèré to tún jẹ́ gbájúgba nínú eré tíátà àti alaga ẹgbẹ́ òṣèré ẹ̀ka ti Tanpan, ọ̀gbẹ́ni Bolaji Amusan, ti gbogbo ènìyàn mọ sí “Mr Latin”

Mr Latin ló sán konko ọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn níbi ètò kan tó tí kópa, ní fèsì sí ọ̀rọ̀ kan tí ó tẹnu mínísítà Orílẹ̀ yìí jáde pé, àwọn òṣèré tíátà ló kọ́ ará ìlú bí wọ́n ṣe ń ṣe òògùn owó.

Ọgbẹ́ni Bolaji Amusan ní ọ̀rọ̀ náà kò rííbẹ̀ rárá, nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ní ènìyàn máa ń mọ ìṣe àti àsà wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn òṣèré wọn.
Amusan sàlàyé àwọn ìmúyẹ tó wà lára àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn eré ti wọ́n máa ń ṣe.

O ní ìdá àadọrùn nínú àwọn olówó orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló máa ń lọ sí ilé Baba Aláwo, àti pé tí ọ̀pọ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ní wo fíímù, wọn kìí wòó parí láti mọ ẹ̀kọ́ tí ó wà níbẹ̀, ni ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn fíímù náà máa ń nàka àbùkù si àwọn tó hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ ni.
Ó ní lẹ́yìn iṣẹ́ sọ́jà, iṣẹ́ eré orí ìtàgé tún ni ó ní àṣà ìbáwí jùlọ, nítorí náà gbogbo nǹkan tí àwọn ń ṣe, ìdánilẹkọ̀ọ́ lo wà fún.

Lóri ọ̀rọ̀ àwọn àgbà òṣèrè ti wọ́n ku ti ọ̀pọ̀ si n ṣe àìsàn, Mr Latin ní, ẹgbẹ́ ńṣe ìwọ̀n to lè ṣe, sùgbọ́n ìhà ti ẹgbẹ́ yóò kọ sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti wà lórí irú ìhà ti ẹni náà kọ sí ẹgbẹ́ nígbà tí ara rẹ̀ jí pépé.

Ní ti Kayode Odumosu tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí “Pa Kasumu” Alága Tanpan ní ẹgbẹ́ ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà láti ìgbà tó ti ṣe àìsàn, eyi o si de ọ̀dọ̀ gómìnà àná ní ìpinlẹ̀ Ogun.

Ó ní nítorí àwọn ìṣèlẹ̀ yìí ni ẹgbẹ́ ṣe fi orúkọ sílẹ̀ fún àwọn ilé iṣẹ́ adójutofò kan láti le jẹ́ kí àwọn ò’sèré le máa fi tọ́rọ́kọ́bọ̀ wọn síbẹ̀ títí di ọjọ́ ogbó wọn ní gbà tí wọ́n ò bá ní le ṣíṣẹ́ mọ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…