Home ÀKỌ̀TUN Pósí ni mo fi ṣe igbá ọṣẹ– Afurasí ọmọ Yahoo Kà bòrò bòrò fún EFCC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 5, 2020

Pósí ni mo fi ṣe igbá ọṣẹ– Afurasí ọmọ Yahoo Kà bòrò bòrò fún EFCC

Pósí ni mo fi ṣe igbá ọṣẹ– Afurasí ọmọ Yahoo Kà bòrò bòrò fún EFCC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọwọ́ ṣìnkún EFCC tẹ àfurasí ọmọ Yàúù mẹ́fà n‘ lbadan

Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, à mọ́ ọjọ́ kansoso péré ni tolóhun, bẹ́ẹ̀ bí irọ́ bá lọ lógún ọdún, ọjọ́ kan soso báyìí ni òtítọ́ yóó ba.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí fún àwọn géńdé ọkùnrin kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n ń lu jìbìtì jẹun, táa mọ̀ sí ọmọ Yàúù, tọ́wọ́ ọ pálábá wọ́n ṣégi nílùú Ìbàdàn.

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ tó ń gbógun ti ìwà ọ̀daràn lẹ́ka owónàá, EFCC fisíta, lójú òpó Instagram rẹ̀ sàlàyé pé, àwọn afurasí ọmọ yàúù tí ọwọ́ tẹ̀ náà jẹ́ mẹ́fà níye.

Àtẹ̀jáde náà ṣọ ọ́ di mímọ̀ pé àdúgbò Oluyọle àti Alao Akala ni ọwọ́ ṣìnkún àwọn òṣìṣẹ́ àjọ EFCC ti ba awọn afurasí ọmọ Yàúù náà, nínú èyí tí obìnrin kan wà láàrin wọn.

Ohun tó wá yani lẹ́nu nípa àwọn afurasí ọmọ Yàúù yìí, ni ti pósí kékeré kan, tó jẹ́ àpótí òògùn abẹnu gọ̀ǹgọ̀ tí wọ́n ká mọ́ wọn lọ́wọ́.

Inú ilé ọ̀kan lára àwọn afurasí oníjìbìtì náà, tí í se ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, ni àwọn òṣìṣẹ́ àjọ EFCC ti rí pósí òògùn ọ̀hún, tó ní asọ funfun nínú, lásìkò tí wọ́n ya bo ilé rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé tó kọjá.

Lásìkò tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò lórí ohun tó ń fi pósí náà se, afurasí oníjìbìtì náà ní igbá ọsẹ ni ohun ń lo pósí kékeré náà fún.

Lára àwọn èròjà tí EFCC rí gbà padà lọ́wọ́ àwọn afurasí oníjìbìtì náà ni ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́rin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ olówó iyebíye àti àìmọye káàdì tí wọ́n fi ń gba owó lẹ́nu ẹ̀rọ tó ń pọwó .

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu Ọrẹ Òtítọ́jù Olùdíje fún i…