Home ÀKỌ̀TUN Ìhòho ni ìyá kan fi s̩é̩gun ogójì Boko Haram
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - March 4, 2020

Ìhòho ni ìyá kan fi s̩é̩gun ogójì Boko Haram

Ìhòho ni ìyá kan fi s̩é̩gun ogójì Boko Haram
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí

Olorun n be bii ti atijo, awa ni a ko sin baba bii t’atijo mo. Ihoho omoluabi ni iya aadorin odun fi sigun si awon boko haram ni ipinle Niger.
Iya yii ni wahala awon eniyan buruku yii ti po ju, ni eyi to mu ki o sigun fun won.
O ko awon odo ilu sodi, o fi nnkan bii efun pa won lese, o fi nnkan pa won loju, o ni ki won tele oun ka lo si inu igbo naa.
Bi won se de inu igbo lo ni ki won yin ibon die sinu igbo ki won le jade. Bayii naa ni awon ode naa se saa bi ologun ti awon boko haram si tu jade ti won si bere si ni yinbon si ara won titi ti ogoji fi ku ninu won,eyi si mu ki ota ibon won jo tan.
Oga awon boko haram to gori igi gan- an fara gba ninu ija naa nitori pe aaye ni won mu oun pelu awon kan.
Opo ohun ija oloro ati ti awon jagunjagun ni won ko ti won si ko gbogbo re fun ijoba ipinle naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …